
Olọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó ti mú àwọn ènìyàn mẹ́fà tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ okunkun nípa bi won ti pa ẹni kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kamoru tí wọ́n tún ń pè ní “Keeper” nínu ìjà Awon elegbe okunkun ní agbègbè Ẹ̀búté Mẹ́tà ní ìpínlẹ̀ náà.
Alukoro ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó, Benjamin Hundeyin, sọ̀rọ̀ yìí nínú Atejade tí ó rán sí Akoroyin wa ní ọjọ́Bo (Wednesday), tí ó ṣàlàyé pé wọ́n mú àwọn ẹni náà ní ọjọ́ ketadinlogun, Oṣù Keje, ọdún 2025, nínu ise iwadi tí àwọn ọlọ́pàá se (Anti-Kidnapping Unit) ní Surulere.
Gẹ́gẹ́ bí Hundeyin ṣe ṣàlàyé, àwọn ẹni tí wọ́n mú ni Raphael Ashim, Wasiu Kareem, Sadiq Olabisi, Olamilekan Oluwatosin, Olalekan Olugbodi, àti Ibrahim Oladimeji.
Ó sọ pé wọ́n fura pé àwọn ẹni yìí ti kópa nínú ọ̀pọ̀ ìjà ní agbègbè náà àti àwọn ibi tó yí ká, èyí tí ó tún yọrí sí ìpaniyan, Kamoru.
Agbenuso ọlọ́pàá náà tún fi kún un pé iwadi ń lọ lọwọ̀ láti mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ okunkun tó sá lọ àti láti gba àwọn ìbọn tàbí ohun ìjà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ wọn.



