Owo te obirin kan ati Awon emewa re ti won puro pe won ji oun gbe mu Ipinle Delta

Ile-ise ọlọ́pàá ipinle Delta ti mú obìnrin kan àti àwọn Akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣe gbimopo lati ji ara wọn gbe, lẹ́yìn tí wọ́n gba owó idola ₦3 mílíọ̀nù.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá fún ipinlẹ̀ Delta, Bright Edafe, lo sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Ajé ní Asaba, olú ìlú ipinlẹ̀ náà.

Edafe sọ pé ọlọ́pàá ń bá a lọ láti ṣàṣeyọrí nínú ogun tí wọ́n ń ja pẹ̀lú àwọn ajinigbé àti àwọn arufin ní gbogbo ipinlẹ̀ ti o yori si bi won ti mu Awon Eniyan yii.

Ó sọ pé:

“Ní ọjọ́ kokanlelogun, oṣù Keje ọdún 2025, a gba ìròyìn pé wọ́n ti jí obìnrin kan gbè ní agbègbè Ajaji (Bonsaac), Asaba.”

Oga Agba ọlọ́pàá Ipinle Delta,Olufemi Abaniwonda, fi àṣẹ fún Kọmandà, Eka Lòdì sí ijinigbe àti jibiti lilu (Cyber Crime), Godwin Osadolor, pé kó gbìyànjú láti gba obìnrin náà là.

Ní ọjọ́ Kejìlélọ́gbọ̀n náà, wọ́n mú ọkùnrin kan, Alfred Elisha, ní Koka Roundabout ní Asaba, àti omiran, Ugochukwu Adim, lẹ́gbẹ̀ẹ́ DLA Road, Asaba.

Nígbà tí wọ́n mú wọn, ọkùnrin náà jẹ́wọ́ pé kii se ijinigbe gidi; pé òun àti obìnrin náà ló gbìmọ̀ pọ̀ láti fọwọ́sowọpọ̀. Oro náà mú kí wọ́n tún mú Merit Eleh, obìnrin tí ó jẹ́ ọdún mokan-din- lọ́gbọ̀n (29).

Gẹ́gẹ́ bí Edafe ṣe sọ, Merit jẹ́wọ́ pé:

“Ó jẹ́ ijinigbe àròsọ, kò sí ijinigbe gidi. A gba mílíọ̀nù meta gẹ́gẹ́ bí owó ìtanrànwọ́. Mo fún àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ní ₦500,000, mo sì gba ₦2.5 mílíọ̀nù fúnra mi.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here