Owo te Afurasi merin, leyin ti omo tun tun di awati ni ile-iwosan, ni ipinle Ekiti.

Ile-ise ọlọ́pàá ni ipinle Ekiti ti so pé wọ́n ti mú ẹni mẹ́rin tìwọ́n ní ọwọ́ lori ọmọ tuntun tí wọ́n n  wa ní ilé ìwòsàn kan ní Ado Ekiti, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

ìṣèlẹ̀ yìí fa ìdarudapọ̀ gidi ní ilé ìwòsàn náà ní Ado Ekiti ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé lẹ́yìn tí won ṣàkíyèsí pé ọmọ tuntun tí won bí ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú di awati.

Enikan sọ pé, “Ìgbà tí àwọn nọọsi tó wà lójúṣe fẹ́ bọ́jú tó ọmọ náà ní òwúrọ̀ ni wọ́n ṣàkíyèsí pé ọmọ tí won bí ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú náà kò sí níbẹ̀ mọ́.”

Elo míì tún jẹ́rìí pé ìpadànù ọmọ náà dá gbogbo ènìyàn lójú ru, ó ní, “Ìṣèlẹ̀ náà dá àríyànjiyàn sílẹ̀ gidi, bí ìyá ọmọ náà, àwọn oṣiṣẹ́ ilé ìwòsàn náà, àti àwọn oníṣòwò to wà lójú ọjà tó wà lẹ́bàá ilé ìwòsàn náà ṣe wà ní ìyàlẹ́nu.”

Nígbà tí a kan si Alukoro Ìbánisọ̀rọ̀ fún ọlọ́pàá Ekiti, Sunday Abutu, ó sọ fún Akoroyin wa pé Kòmíṣánà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Joseph Eribo, ti pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti kópa kánkán nínú oro náà kí wọ́n sì rí dájú pé wọ́n ri ọmọ náà pada.

Abutu sọ pé, “Kòmíṣánà ọlọ́pàá ti paṣẹ pé kí Ẹka Ìwádìí Ẹ̀sùn Ọdaràn ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ takuntakun láti rí ọmọ náà padà.

“Ní báyìí, wọ́n ti mú afurasi mẹ́rin tìwọ́n ní ọwọ́, wọ́n sì ti ń fún wa ní àlàyé tó dájú tó máa ràn wa lọ́wọ́ nínú ìwádìí ọ̀ràn náà.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here