
Àwọn olópa ni ipinle Akwa Ibom ti mú àwọn ọkùnrin mẹ́ta ti wo fura sí pé wọ́n jẹ́ adigunjale , wọ́n sì tún gba àwọn ibọn lọ́wọ́ wọn ní ìlú Uyo.
Nínú ìkéde tí Alákóso Ìbánisọ̀rọ̀ fún ile-ise Olópa naa so, DSP Timfon John, ṣe lọ́jọ́ isegun, ó sọ pé àwọn Afurasi náà ló ti sose oríṣìíríṣìí, Awon iwa odaran tó ga jùlọ nínú ìlú náà.
John ṣàlàyé pé mimu náà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìwádìí tó péye, èyí tó yọrí sí bi won ti mu ẹni kan, Ubong Patrick, ará ìlú Ikpa Ibiono, ni agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ibiono Ibom.
Ó sọ pé ẹni náà, jẹ́wọ́ ẹ̀sùn náà nígbà iforowero, o si mu àwọn olópa lọ́ síbi tí wọ́n ti mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjì tó kù: Ibrahim Kanu, ará ìlú Gorore nípò Adamawa State, àti Nazipi Dahiru.
John so pe Ní ọjọ́ Kejìlá, Oṣù Kẹjọ ọdún 2025, ní àgogo méje òwúrọ̀, obìnrin kan tó ń gbé ní Sampson Akpan Street, Uyo, lọ sọ́dọ̀ ọlọ́pa pé nígbà tó ń rìn ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ Believers Assembly Road níbi tí ó sunmọ́ Udo Udoma Avenue, àwọn ọkùnrin méjì tó ní ibọn ló dé lona Lori okada.
“Àwọn olè náà fa ibọn won yo, wọ́n sì jí iPhone 12 Pro ti owo re tó N650,000 lọ́wọ́ rẹ̀. Ìwádìí tó tẹ̀síwájú ṣàfihàn pé awon olè yìí ló tún jí nkan àwọn aráàlú márùn-ún míì lọ́jọ́ náà.
“Nígbà iforowero, ó jẹ́wọ́ pé ó kópa nínú isele náà, ó sì si mu àwọn olópa lọ́ síbi tí wọ́n ti mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ méjì tó kù: Ibrahim Kanu àti Nazipi Dahiru. Àwọn méjèèjì ń gbé ní agbègbè ‘Nassarawa’, tó wà ní Itam, Itu LGA.”

