
Ko din ni eyan meta-din-ladota (47)ti EFCC fura pe wọn jẹ́ onijibiti lori Ero ayelujara ni ipinlẹ Edo ti wọn ti mu
Ile-iṣẹ EFCC ni ẹka Benin sọ̀rọ̀ yii ninu ìkéde kan lori oju opo X ní ọjọ́ Jímọ̀, tí wọ́n tún sọ pé ìbọn “pump action” àti àwọn kátíríjì ìbọn ní wọ́n gba lọ́wọ́ ọkan ninu wọn.
Àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Amu wọn ní ọjọ́ Jímọ̀,ojo kedogun, Oṣù kejo, ọdún 2025, leyin olobo tó dájú pe won se iṣẹ́ ìtanjé lori ayelujara.
“Àwọn ohun mìíràn tí a gba lọ́wọ́ wọn ni: ọkọ ayọ́kẹ́lẹ̀ mẹ́fà, fónú alágbèéká, àti kọ̀ǹpútà alagbeletan (laptop).
“Wọ́n máa dá wọn lẹ́jọ́ lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí.”
Ile-iṣẹ náà tún sọ pé ní ọjọ́ Àìkú, wọ́n ti mu àwọn ènìyàn meta le ni Aadorun (93) tí wọ́n fura sí ní ipinle Ogun gẹ́gẹ́ bí onijibiti lori Ayelujara na pelu.
Wọ́n ṣàlàyé pé mimu wọn waye nígbà ìkọlu àkọsílẹ́ kan ní Abeokuta, ìlú olú-ìpínlẹ̀, lẹ́yìn olobo tó dájú tó so wọn pọ̀ won se ise ìtanjé lori ayelujara.



