
Gómìnà ni igba kan ri ni ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom, ti sọ pé kò korira Ààrẹ Muhammadu Buhari tó kú, nípa bí ìjọba rẹ̀ ṣe tọ́jú ààbò ní agbègbè North Central.
Alága ní ẹgbẹ́ Peoples Democratic Party lo sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Ajé, ní àkókò ìfọrọwérọ̀ kan lórí eto Politics Today tó wà lórí Channels Television.
Ortom sọ pé kì í ṣe pé ó kórìíra ìjọba Buhari, ṣùgbọ́n pé ó kan ń sọ pé ìjọba náà kò ṣe tó pé nípa ààbò ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ ní àsìkò yẹn.
Ó ṣàlàyé pé òun ní láti sọ òtítọ́ kí ó lè dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ó ní, “Mi ò kórìíra Buhari, mi ò kórìíra ìjọba rẹ̀, mi ò kórìíra Fulani kankan. Ohun tí mo wà fún ni pé wọ́n dìbò yàn mi kí n dáàbò bo àwọn ènìyàn mi, kí n sì tọ́jú wọn.”

