
Kọmissọna fun Ẹka Irinna oko Oju popo (commissioner for transportation) ìpínlẹ̀ Kano, Alhaji Ibrahim Namadi, ti kowe fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ ní lẹ́yìn tí Gomina Abba Yusuf gba leta láti ọ̀dọ̀ Awon tó ń ṣàwárí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Awon to ta ati gbe ogun oloro, Sulaiman Danwawu.
Namadi kede leta ifisesile yìí nípa fífi àtẹjáde kan síta, tí Olùdarí fún Ìbánisọ̀rọ̀ ni Ilé Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano, Sanusi DawakinTofa, fọwọ́ sí ní ọjọ́rú.
Ó ṣàlàyé pé ìpinnu rẹ̀ láti fi ipò náà sílẹ̀ jẹ́ títẹ̀síwájú fún ìfẹ̀ àwùjọ àti Awon oun to nínú ọ̀ràn náà.
Ó ní:
“Gẹ́gẹ́ bí Okan Lara ọmọ ẹgbẹ́ ìjọba tí ó lòdì sí títà àti lílò oògùn oloro, ó yẹ kí n gbìyànjú láti gbe ipò yìí silẹ—bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dun mi gan-an.
“Bí mo ṣe ń tẹ̀síwájú pé mi ò ní esun abi pe mio mo nkan kan nipa isele na, mi ò le foju kọ bó ṣe jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń wo mi pẹ̀lú iwoye àti pé Mo nilo lati dabo bo ise takuntakun ti ati se.
Nínú àtẹjáde náà, Namadi dúpẹ́ lọwọ Gomina ìpínlẹ̀ Kano, Abba Yusuf, fún àǹfààní tó fún un láti ṣèrànṣẹ́ fún ìpínlẹ̀ náà.
Ó ní:
“Gẹ́gẹ́ bí ọmọ orílẹ̀-èdè rere, ó yẹ kí n gbìyànjú láti dáàbò bo, kí n sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ànfààní tí a ti ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mú wà sí ìpínlẹ̀ wa.”

