Iro lasan ni iyan si ipo ti Aare Tinubu yan, Ogbon oselu ni (ADC lo so be)

Ẹgbẹ́ African Democratic Congress (ADC) ti so pe ikede ti Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe nípa yíyàn àwọn olùdarí gẹ́gẹ́ bí “ìsapá pajawiri láti rà igbàgbọ́ àwọn ará ilẹ̀ Àríwá padà, lẹ́yìn tí ó ti bà á jẹ́ fún ọdún kan kọja.”

Nínú ìkéde tí agbẹnusọ àgbà Egbe ADC, Mallam Bolaji Abdullahi, fọwọ́ sí, ADC sọ pé yíyàn àwọn olùdarí tuntun yìí jẹ́ “kékèké, Ati eleyi to ti pẹ́ ju,” ó fi kun pé “ìwọ ò le ṣe àbùkù ẹ̀ka ilẹ̀ kan fún oṣù marunlelogun, kí o sì retí kí wọ́n yìn ọ́ lójú pé o rántí won ní oṣù kerindinlogbon pé Nàìjíríà tóbi ju Ìpínlẹ̀ Èkó lọ.”

Gẹ́gẹ́ bí ADC ṣe sọ, yíyàn tuntun yìí je “ìṣàkóso nǹkan iberu fún ìbò ton bo lona,” ìsapá pajawiri láti bo ìjàmbá tó ti ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Àríwá Nàìjíríà látàrí yi-yanni-ni-iposi, iwa atobi ma se bawi àti ojusaju.

Fún ju ọdún kan lọ, ìjọba yìí Ko Ko ojú si àwọn ajinigbé ṣe ń da Àríwá lamu, bí àwọn agbẹ̀ ṣe fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀, àti bí àwọn ilé-iṣẹ́ agbègbè ṣe ń bàjẹ́ látàrí àyípadà subsidy epo tí kò lágbára àkànṣe,” ni Abdullahi sọ.

Ní báyìí, pẹ̀lú ìfèsèyin àwùjọ tó ń pọ̀ sí i, àti pẹ̀lú ìfarahàn àwọn alatako tó lágbára tó ń gbòòrò káàkiri Àríwá àti gbogbo orílẹ̀-èdè, Ààrẹ Tinubu sa dede rántí pé àwọn ará Nàìjíríà mìíràn wà lórílẹ̀-èdè yato si Àwon ti wọn jẹ́ ti Èkó Abi bẹ́ẹ̀ kọ.

Ṣùgbọ́n àwọn ará Àríwá tí wọn jẹ́ alajoni ati alajosepo orílẹ̀-èdè wa ń rí kedere pé a kò lè tan wọ́n jẹ. Wọn ń rí ohun tí Ààrẹ Tinubu ń ṣe – wọ́n sì mọ̀ pé ohun tí ó ń ṣe kì í ṣe tòótọ́.àfiwé kì í ṣe ìṣàkóso,” ni agbẹnusọ ADC sọ.

ADC kéde sí ìjọba Tinubu pé kó fọwọ́ sẹ́yìn láti máa ṣe “ìṣàkóso Bourdillon,” kí ó sì bẹrẹ ìṣọkan orílẹ̀-èdè tòótọ́ pẹ̀lú ìmọ̀ràn, òdodo nínú ẹ̀tọ́ òfin, àti mímú abáyọ kíkún nípa àmúlò Federal Character lai si Oju saju.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here