
Àgbà Ilú Ibadan, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ẹgbẹ́ Olúbàdàn (Olubadan-in-Council), yóò bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa fífi Ọba Rashidi Ladoja je gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn Ibadan elekerin-le-logoji (44th) ní Ọjọ́ Ajé.
Ìpàdé yóò wáyé ní ààfin Olúbàdàn tó wà l’Ọkẹ́-Arẹmọ, ni Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìbàdàn North, ní ago mokonla aro (11:00 a.m.).
ipàdé yìí tí Ọba Tajudeen Ajibola, Balógun Ibadan, fi síta ní Ìbàdàn, l’Ọjọ́bọ̀, sọ pé: “Ìpàdé yìí wáyé lẹ́yìn tí àkókò idaro ọjọ́ Mokonlalogun (21 days) fún Ọba tó kọjá lọ, Ọba Owolabi Olakulehin, parí.”
Gbogbo àwọn olórí-ìlú àgbà Ibadan ló yẹ kí wọ́n wà níbẹ̀.
Ìwé iroyin Ekeibidun ti jẹ́ kó dájú pé Ladoja máa padà sí Ìbàdàn l’ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí.
Ó ti ń gba àwọn alejo l’ílẹ̀ rẹ̀ ní Eko (Lagos) látìgbà tí Ọba tó olukulehin ti fi ayé sílẹ̀.

