
Ile ise olopa ni ipinlẹ Delta ti mu okunrin kan, ẹni ọdun metadinlogbon (27),Kelvin Obakpororo, lẹ́yìn tó pa Iyawo rẹ̀, iya ọmọ méjì tó jẹ́ Excellence.
Agbẹnusọ olopa ni ipinle Delta, SP Bright Edafe, lo sọ̀rọ̀ yi ni Asaba ní ọjọ́ Àìkú.
Ó ní “Ẹ rántí pé láàárin ọjọ́ kẹrìndinlogbon Ati ojo ketadinlogbon [June 26-27, 2025], Oju opo àgbáyé (social media) kun fún ìròyìn ni pa pipa obìnrin kan tó jẹ́ Excellence ní Sapele, eleyi tí ọkọ rẹ̀ tó pa.
“Ọkùnrin náà sá lọ ni Igba ti isele na sele, ṣùgbọ́n a ti mú un. Ó wà nínú agọ́ wa bayii.
“Fún gbogbo ẹni tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ìdájọ́ ododo fún Excellence, ẹ je mọ̀ pé a ti mú ẹni tó ṣe ise ibi oun, a ó sì gbé e lọ sí kóòtù laipẹ̀.”
Nígbà tó ń jẹwọ̀ ẹ̀sùn naa, Kelvin sọ pé ó wa labẹ́ ipa oògùn tó mu ti oun Ko si mo oun ti oun se mo.
Ó ní isele na sele toripe Iyawo oun “Ó máa ń ṣe hook-up. Nígbà tí ó wá sílé mi, ó máa wa paro aṣọ kí ó le lọ pàdé ọkùnrin mìíràn. Ní ọjọ́ yẹn, a bá ara wa ja. Ó mú ọbẹ, èmi náà mú hammer.
“Lẹ́yìn tí mo borí rẹ, mo fi hammer lu ori rẹ lẹ́mẹta. Ó ṣubú, ó kú.
“Mi ò mọ̀ pé ó máa kú, mo wa labẹ́ oògùn (200mg tramadol).Mo jẹwọ̀ pé aṣìṣe ni. Ó bímí ọmọ méjì fun mi— ọmọ ọdún meta ati méjì ọdún.”



