
Ile-ise olọ́pàá ipinle Ogun ti pa àwọn ajinigbe méjì nínú ita poro gan ibọn ní agbègbè Owode-Egba ni ipinlẹ̀ náà.
Eleyi ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba àwọn ènìyàn mẹ́ta tí won jigbe ní ìlú Ajebo ni ọjọ́ kerindinlogun oṣù Keje, tí wọ́n sì gba wọ́n nínú igbó láì farapa.
Ní gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Alukoro ọlọ́pàá ipinlẹ̀ ogun, Omolola Odutola, ni alẹ́ Satide, wọ́n sọ pé àwọn Ajinigbe wọ̀ ìlú Ajebo kí wọ́n tó jí àwọn aráàlú mẹ́ta gbe lọ́sẹ̀ yẹn.
Odutola sọ pé Kòmíṣọ́nà ọlọ́pàá, Lanre Ogunlowo, rán ẹgbẹ́ ọlọ́pàá tí wọ́n ń ṣàkíyèsí Ati Dena àwọn Ajinigbe lọ inu Igbo na lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba Àwon eyan oun.
“Iṣẹlẹ̀ náà ni wọn ji ènìyàn mẹ́ta gbà ní agbègbè Ajebo, tí ó wà lábẹ́ agbègbè ọlọ́pàá Owode-Egba. Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé si ibi isele oun. Ni Àwon Ajinigbe yi Ko Oju ibon si Àwon olopa ti Àwon na si SA pada fun won,Níbi gbígba ibọn náà, àwọn odaran oun méjì kú, àwọn mìíràn sá lo pẹ̀lú ìfarapa ota ibọn.”
Odutola tún sọ pé àwọn nǹkan tí wọ́n rí níbi iṣẹlẹ̀ náà ni: ibọn AK-47, àdá kan, sekeseke pẹ̀lú agada godo tí wọ́n fi n de eni àwọn tí wọ́n jí gbà, fónù alágbèéká kan, àti owó to jẹ́ N1,200,035, ti o see se Ko je owó ti won gbe lowo Àwon ti won ji gbe.

