
Gómìnà ni igba kan ri ni Ìpínlẹ̀ Ogun àti aṣojú Ìlà Oòrùn ipinle ogun , Otunba Gbenga Daniel, lỌjọ́ Ajé, bu ọlá fún ìṣàkóso ti Aláyélúwà Awùjalẹ̀, Ọba Sikiru Kayode Adetona, nípa àpejuwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ti kì í bẹ̀rù láti sọ òtítọ́.
Otunba Daniel tún sọ pé ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jùlọ láti bu ọlá fún ọba tó jẹ́ fún ọdún marunlelogota (65) ni pé kí won ṣẹ̀dá ìpínlẹ̀ tuntun kúrò nínú agbègbè Ijẹ̀bú àtijọ́, torí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àlá rẹ̀.
Otunba Gbenga Daniel sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní Ijẹ̀bú Òde ní Ọjọ́ Ajé.
“Mo rántí pé Kabiyesi Awùjalẹ̀, Ọba Sikiru Kayode Adetona, jẹ́ ẹni tó lè sọ òtítọ́ sí àwọn tó wà lórí àga akoso. Ó jẹ́ ẹni tí kò ní kẹ̀gàn, tí kò ní i fi ọrọ̀ pamọ́, tí ó sì jẹ́ ọlọ́tọ̀ sí gbọ́gbọ́ eniyan .”
“Kabiyesi máa ń sọ bí ohun ṣe rí. Nítorí èyí, ó ní àwọn olùkórìíra rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ìparí, gbogbo ènìyàn mọ̀ pé ó bori gbogbo won.
Daniel fi kun pé “Gbogbo àwùjọ gba pé kí ìpínlẹ̀ tuntun wa. Lati odun 1924, Ijẹ̀bú Province nikan ni wọ́n kò tíì yí padà sí ìpínlẹ̀ tuntun, àti pé nítorí èyí, gbogbo ènìyàn gbagbọ́ pé àṣìṣe yìí gbọ́dọ̀ je títúnṣe.”
A mọ̀ dájú pé kì í ṣe oun to rọrùn láti dá ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀. Ó ní àwọn awuyewuye, ariyan jiyan,ìfọwọ́sowọpọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Oni a ní ireti pé kíákíá, pàápàá báyìí tí Kabiyesi ti kúrò ní ayé, gbogbo àwọn olórí yóò lò àǹfààní yìí láti bu ọlá àti láti fi ìpínlẹ̀ tuntun fi ma se ìrántí fún Ọba Adetona.”

