
Egbe àwọn Olùkọ́ni Yunifásítì ti ilẹ̀ Nàìjíríà (ASUU), ẹ̀ka ti ile eko giga ti Maiduguri, ti fi aidunu won han àti fariga Loro bi ijoba apapo ti yi orúkọ Yunifásítì Maiduguri sí orúkọ Ààrẹ Muhammadu Buhari tó kú, wọ́n sì ti sọ pé wọ́n máa gbìyànjú lórí ọ̀nà òfin láti lo ile-ejo.
Nínú ìkéde tí wọ́n fi lede ní ọjọ́ Jímọ̀, tí Alákóso wọn, Abubakar Mshelia, àti Akọ̀wé, Peter Teri, fọwọ́ sí pọ̀, ASUU-UNIMAID sọ pé ipinnu yìí wáyé lẹ́yìn ìpàdé pajawiri tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ kerin-le-logun, osu keje, ọdún 2025.
Gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ, àwọn olùkó, aṣojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àti àwọn míì tó ṣe pàtàkì wà ní ìpàdé yìí.
Wọ́n sọ pé lẹ́yìn ipade na, gbogbo wọn fọwọ́ sí i pé kí orúkọ tuntun yìí lo, kí wọ́n sì yípadà sí orúkọ àtẹ̀yìnwá.
Ajo ASUU sọ pé “Lẹ́yìn iforojomitoro oro, ipade náà pinnu pé won kọ́ fe orúkọ tuntun tí wọ́n pe Yunifásítì Maiduguri sí Muhammadu Buhari University, Maiduguri.
“Ipinnu yìí jẹ́ pé orúkọ tuntun yìí jẹ́ àkíyèsí ipalara fún òmìnira ilé-ẹ̀kọ́ gíga ma.
Wọ́n tún sọ pé ASUU UNIMAID ti fi àṣẹ fún olùdarí wọn láti tọ́pa gbogbo ọ̀nà òfin tó wà, kí wọ́n lè da ìpinnu yìí dúró, kí wọ́n sì dáàbò bo orúkọ ilé-ẹ̀kọ́ náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti mọ̀ ọ́.
Wọ́n sọ pé:
“Àǹfààní àti ìdúróṣinṣin ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dara, kí ìṣèlú má bà á jẹ́.”

