Àwon olugbe Agbegbe Sowo ni ipinle ogun ti bere iwode Lori iku Àwon Akeko merin ti oko pa

Àwọn ará agbegbe Sowo ni ipinle ogun kan ti bínú, wọ́n sì dá opopona Abeokuta–Sagamu dúró láti fi hàn pé wọ́n bínú sí ìpàdànù àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ alakọ́ọ́bẹ̀ Iddo Primary School, Kobape, ipinle ogun, mẹ́rin tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan pa lójú-ọ̀nà ní ojoru .

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀jọ́ méjì ti oko kan ti pa olokada Ati ero re àti ero ti o gbe seyin rẹ̀ ní Siun, lórí opopona kan náà.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, ìjàmbá náà ṣẹlẹ̀ ní agogo mẹ́ta ọ̀sán (3pm) nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan wọ àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ wọ́n nígbà tí wọ́n ń padà lọ sí ilé lati ilé-ẹ̀kọ́.

Àwọn ènìyàn kan sọ pé àwọn ọdọ́kùnrin kan gbìyànjú láti lu awakọ̀ ọkọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá gba lọ́wọ́ won.

Agbenuso fun Eto irina ni ipinle ogun TRACE, Babatunde Akinbiyi, fidi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀. Ó ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Corolla pelu nọ́mbà KSF 579 DM kolu àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ mẹ́rin náà tó sì pa wọ́n lójú-Ese.

Gẹ́gẹ́ bí Akinbiyi ṣe sọ, wọ́n gbé àwọn ọmọ náà lọ sí Iléewosan ijoba to wà ní Ijaiye, níbi tí wọ́n so pé wọ́n ti kú.

Ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó rí bi iṣele na se ṣẹlẹ̀ sọ, ọmọkùnrin mẹ́rin látinú Iddo Primary School wà lójú-ọ̀nà tí wọ́n ń padà sílé, nígbà tó jẹ́ pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Corolla kan tó ń sare ju bó yẹ lọ, ló wọ́ inu wọ́n, tó sì pa wọ́n níbẹ̀.

Akinbiyi tún sọ pé àwọn aráàlú kan bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Ehonu han, wọ́n sì dá opopona náà dúró, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá, TRACE àti ọmọ ogun ṣiṣẹ́ pọ̀ láti sọ ohun gbogbo di mímu Bo pada sipọ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here