
Àwọn obìnrin agbábọọlu Nàìjíríà, Super Falcons, ti bori Morocco pẹ̀lú bi wọ́n ti padà bọ láti eyin, tí wọ́n ṣẹgun pelu ami ayo meta si meji 3–2 nínu idije Ife eye ile adulawo ti Awon obirin Loni Satide ti won fi gba Ife eye na.
Morocco kọ́kọ́ gbé bọ́ọ́lù wọ́lé ní dede ìṣẹ́jú kejila (12th minute) nípasẹ̀ Ghizlane Chebbak. Wọ́n tún fi ìkejì kún ún ní ìṣẹ́jú kẹrìnlọ́gun (24th minute) nípasẹ̀ Sanaâ Mssoudy.
Ṣùgbọ́n Nàìjíríà padà wa ni abala Keji ti o si so eso rere.
Esther Okoronkwo ni o koko mi Awon ní ìṣẹ́jú kẹrìnlelogota (64th minute) láti mú kí ó di 2–1. Lẹ́yìn náà, Folashade Florence Ijamilusi gba bọ́ọ́lù kan wọ́lé ní iseju mokanleladorin (71st minute) láti ṣe 2–2.
Jennifer Echegini sì gba awọ́n mi wole lati ṣẹgun pátápátá ní ìṣẹ́jú mejidinladorun (88th minute).

