
Àjọ Àwọn Gómìnà ni Ìpínlẹ̀ Àríwá (NSGF) ti fi ìbànújẹ hàn lórí ikú omo orílẹ̀-èdè yi kan Eni ti se minisita ni Igba kan ri fun Ọ̀rọ̀ Ogbìn àti Ìdàgbàsókè Àgbègbè, Ṣíìfù Audu Ogbeh.
Ajo Akoroyin orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà (NAN) ròyìn pé Ogbeh kú ní ọjọ́ Sátidé ní eni ọdún mejidinlogorin (78).
Alaga àjọ náà, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Gombe, Inuwa Yahaya, sọ̀rọ̀ yìí nínú ìkéde ìtùnú tó fi jáde nípasẹ̀ Olùrànlọ́wọ́ Rẹ̀ nípa Ìròyìn, Ismaila Uba-Misilli, ní ọjọ́ Sátidé ní Gombe.
Yahaya ṣàpèjúwe Ogbeh gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn olóṣèlú àgbà, olóòtọ́ orílẹ̀-èdè tó ní ọgbọ́n.
Ó sọ pé Ogbeh fi gbogbo ayé rẹ̀ sise fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn.
“Audu Ogbeh jẹ́ olórí tó ni aseyori, olóṣèlú tó ní ìrírí àti eko nipa ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ìmọ̀, ètò tí ó fi sílẹ̀ nínú ìrìnàjò ìjọba àti ìdàgbàsókè Nàìjíríà yóò wà láé ninu ìtàn.
Alaga NSGF sọ pé ikú Ogbeh jẹ́ oun tó lágbára kì í ṣe fún Benue àti Àríwá nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo orílẹ̀-èdè pátápátá.
“Gẹ́gẹ́ bí Alaga Àjọ Àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ Àríwá, mo darapọ̀ mọ́ ìjọba àti àwọn ènìyàn Benue, ìdílé Ogbeh àti gbogbo orílẹ̀-èdè láti sọ ìbànújẹ wa lórí ìpàdánù olóòtọ́ ará Nàìjíríà,” ni ó sọ.
Yahaya sọ pé Ogbeh, tó tún jẹ́ Ààrẹ tele ri ninu Ẹgbẹ́ Òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), fi ẹ̀tọ́ orílẹ̀-èdè, ìmọ̀ jinlẹ̀, ìwà ìrẹ̀lẹ̀, sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí tó lágbára.

