Àwọn ara ipinle Ọ̀yọ́ Pè Fún Ìparí Àṣà dida abe fun Obìnrin (FGM)

Igba (200) lára àwọn agbegbe ni ipinle Ọ̀yọ́ ti pe fún pípa àṣà dida abe fun omobìnrin (Female Genital Mutilation) kúrò nínú àwùjọ.

Olùdarí fun Egbe Trailblazer Initiative Nigeria, Dàré Ọlágòkè-Adáràmọ́yé, so eyi ní ìpàdé ọ̀sẹ̀ kan tí ẹgbẹ́ náà ṣètò pẹ̀lú UNICEF àti Ẹka Ìbáṣepọ̀ àti Ìdábòbò àwọn Obìnrin àti Àwọn ènìyàn Aláìlera nípò àwùjọ, ní ọjọ́ Sátidé ní Ìbàdàn, olú-ilu ìpínlẹ̀ náà.

Ọlágòkè-Adáràmọ́yé ṣàlàyé pé ìpàdé náà wáyé pẹ̀lú àwọn olórí àdúgbò, pẹ̀lú àwọn ọba, àwọn alufa àti olórí ìjọ, àwọn obirin, àti aṣojú àwọn ọmọde àti ọdọ lati àwọn agbègbè ati ijoba ibile bi Ido, Oluyole, Olorunsogo, àti Saki.

Ó ní “ipade náà dá lórí fífi ikede fun gbogbo àwọn eewu tó wà nínú dida abe fun omobirin bíi àwọn ìlera tó burú jùlọ, ìfarapa ọkàn, àti àwọn ìyọnu tó wà nínú òfin (violence against persons prohibition law) VAPP tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbé kalẹ̀.”

Ótun so pe “Nígbà tí àwọn ọba, àwọn olórí, àwọn imámù, àwọn pástọ̀ àti àwọn obìnrin oríta sọ pé ‘Ó tó gé!’, àwùjọ agbọ́.”

Mojisola Omotoye, tó jẹ́ Alákóso Ètò fún TBI, ṣàlàyé pé àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn gege bi Oloye yóò jẹ́  wọ́n yóò sì jẹ́ olùkọ́ ati ma fi àǹfààní fún àwọn eyan ni agbegbe.

Ọba Bashir Abioye (Siyanbola IV), Onigbeti ti ilẹ̀ Igbetiland, sọ pé ó ń setan atilẹ́yìn fun àfihàn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here