Àwọn ará ìlú Lafia, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Nasarawa, ń bẹ nínú ìbànújẹ àti ìbẹ̀rù gidi, nítorí àwọn ajinigbé tí ń gbe àwọn olùgbé

Àwọn ará ìlú Lafia, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Nasarawa, ń bẹ nínú ìbànújẹ àti ìbẹ̀rù gidi, nítorí àwọn ajinigbé tí ń gbe àwọn olùgbé, kí wọn sì bèèrè owó ìtanràn miliọnu naira.

Ọkan lára ​​àwọn tí wọ́n jigbe ti Ori Ko yo, tó bá wa sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ó bẹ̀ wa pé ká má darúkọ rẹ̀, ṣàlàyé ìrírí tí ó ní lára jùlọ. Ó sọ pé wọ́n gbe níwájú ilé rẹ̀, tí wọ́n sì gbé e lọ su inu Igbo to jìnnà pẹ̀lú ibon ni owo wan.

“Mo fẹrẹ́ wọ ilé ni wọ́n bá mi, àwọn ọmọkùnrin kan wí pé kí n dúró. Wọ́n mú mi lọ ní agogo mẹjọ kọjá aadota alẹ́ (8:50 p.m.) pẹ̀lú ibọn. A rìn fún bí wákàtí mokonla(11 hours),” ni ó sọ.

Ó sọ pé àwọn tó gbe oun jẹ́ àwọn Fulani tó gbọ́ ede wọn. Wọ́n na oun gan-an, wọ́n sì sọ fún un pé bí ó bá pé ọlọ́pàá, wọ́n á pa á. Kó tó le bọ̀ láàyè, ẹbí rẹ̀ ní láti kó owó miliọnu wa kí wọ́n tó dá a sílẹ̀.

“Mi ò mọ ohun tí mo ṣe tó fi jẹ́ pé wọ́n ṣe mi báyìí. Ẹbí mi gbe gbèsè láti gba mí padà,” ni ó sọ pẹ̀lú ìkànsí.

OMiíràn tó tún jẹ́ Eni ti won jigbe ní Lafia náà sọ pé àwọn ajinigbé náà ní agbára púpọ̀, wọ́n sì mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. “Wọ́n ní àwọn tí ń fún wọn ní ìròyìn. Wọ́n gbé mi si Doma Barracks títí tí wọ́n fi gba owó tanràn. Nàìjíríà ti wa ninu ìṣòro gidi,” ni ó sọ.

Àwọn ará ìlú sọ pé àwọn agbègbè bíi Lafia North, Polytechnic àti College of Agriculture, Shabu, Danka, Tudun Kauri, Tudun Amba àti Kwandere ni àwọn isele yii ti burú jùlọ báyìí.

Wọ́n béèrè fún àfikún ọlọ́pàá, kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kẹkẹ́ Maruwa àti okada, kí wọ́n sì fọ́ àwọn ìbáṣepọ̀ ajinigbé yà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here