
Alákóso Tele ri fun Egbe All Progressives Congress (APC), Dókítà Abdullahi Ganduje, ti kéde ayọ̀ rẹ̀ bi ojogbon Nentawe Yilwatda Goshwe lori bí wọ́n ṣe yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí tuntun ẹgbẹ́. Ó ní yíyàn rẹ̀ péṣé ni àkókò tó yẹ, tó sì ṣe pàtàkì gan-an.
Nínú ìkéde tí Ganduje fọ́wọ́ sí lọ́jọ́bọ, ó sọ pé yíyàn Yilwatda wá nígbà tó ṣe pàtàkì jùlọ fún APC, ó sì ní òun ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ pé Prof. Yilwatda máa darí ẹgbẹ́ náà lọ síbi tó dáa.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ:
“Yi yan ojogbon Yilwatda wà ní àkókò tó yẹ. Ó jẹ́ àkókò pàtàkì fún ẹgbẹ́ wa. Mo ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú ọgbọ́n rẹ̀, ìmúlò rẹ̀, ìrírí àti agbara rẹ̀ láti gbé ẹgbẹ́ wa sókè.”
Ganduje, tó tún jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano tẹ́lẹ̀, yìn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àgbà àti ìgbìmọ̀ APC tó darí yíyàn naa, pé wọn ṣe iṣẹ́ tó mọ́, tó sì fi hàn pé àjọṣepọ̀ àti ìbò àgbàláyé wà nínú ẹgbẹ́ naa.
Ó tún bu ọlá fún Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu àti Igbakeji rẹ̀, Kashim Shettima, pé wọ́n ṣe ohun àgbà nínú yíyàn tuntun.
“Ààrẹ wa àti Igbakeji rẹ̀ ti fi hàn pé wọ́n ní ọgbọ́n àti amójútó nínú iṣẹ́ ẹgbẹ́ wa. Ìmúrasílẹ̀ wọn láti mú àjọṣepọ̀ àti àlàáfíà wá sí APC wúlò gan-an. Mo sì ń pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ kí wọ́n fi ọwọ́ kun olori tuntun yìí, kí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ papọ̀ láti mú ‘Ètò Ìrètí Tuntun’ Ààrẹ wa ṣẹ,” ni Ganduje sọ.

