Alaga EFCC ni wọ́n ń retí pé yóò sọ̀rọ̀ pàtàkì ní ibi àpéjọ ìjíròrò lórí idokowo ile ati ile (real estate) ní Nàìjíríà.

Alága Ẹgbẹ́ Ajo tondi si isowo ilu kumo kumo (EFCC), Ola Olukoyede, ni wọ́n ń retí pé yóò sọ̀rọ̀ pàtàkì ní ibi àpéjọ ìjíròrò lórí idokowo ile ati ile (real estate) ní Nàìjíríà.

Ilé-ise ofin tí wọ́n ń pè ní Law Corridor ló ṣètò àpéjọ yìí, tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹjọ ọdún 2025 ní Abuja.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹjáde kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Akoroyin wa ṣe sọ, àpéjọ yìí jẹ́ apá kan nínú ìpàdé àkànṣe tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kẹ̀rin-ọdún tí Law Corridor ń ṣe, tí yóò sì kó àwọn alábàṣepọ̀ jọ láti ọ̀dọ̀ ìjọba àti aládani láti sọ̀rọ̀ lórí ètàn tó wà nínú ọjà ilé.

Àtẹjáde náà sọ pé:

“Àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tí wọ́n máa jíròrò lórí ni tita ilé tìkára ẹni, àwọn alákóso ilé tí kò ní ìyàsọ́tọ̀, àwọn oníṣe èké tó ń dá ilé tà, ìṣòro tó wà nínú mímu ofin tọ̀, bí wọ́n ṣe máa borí fífi owó ètàn wọ ọjà ilé.

“Àwọn tí wọ́n ti fọwọ́sowọpọ̀ pé wọ́n máa wà níbẹ̀ ni:

Alakoso àgbà tó wà lórí FCDA (Federal Capital Development Authority), Engr. Richard Yunana Dauda.

Olùdásílẹ̀ ilé-ise ofin Omaplex, Oyetola Muyiwa Atoyebi (SAN).

Olùdásílẹ̀ ilé-òfin Afe Babalola & Co., Kehinde Ogunwumiju (SAN).àti Olùdarí SCUML (Special Control Unit Against Money Laundering), Harry Erin.”

“Àwọn tó ṣètò àpéjọ náà sọ pé wọ́n máa dá àkójọ ìmòràn àti ọ̀nà tí wọ́n lè gbà tún ọjà ilé ṣe sílẹ̀ lẹ́yìn àpéjọ náà, tí wọ́n á sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ọfiisi ìjọba tó yẹ kó tàn án.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here