
Ìpínlẹ̀ Kano ti setan láti gba Ààrẹ Bola Tinubu lójó Jímọ̀ (òní) láti kedun pelu ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kano, àti fún ìdílé baba ọlọ́rọ̀, àti aláàánú, Alhaji Aminu Dantata.

Èyí wà nínú àtẹjáde tí agbẹnusọ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Sunusi Tofa, fi síta ní ọjọ́bọ.
Ìbẹ̀wò náà wáyé lẹ́yìn ikú Alhaji Dantata, ẹni tó jẹ́ olóṣèlú àti oníṣòwò ńlá.
Tofa sọ pé ìbẹ̀wò Ààrẹ yìí jẹ́ àfihàn ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè àti ìbùkún fún àwọn ènìyàn Kano àti iranti rere Alhaji Dantata.
Ó pè àwọn ará Kano láti gbà Ààrẹ wọlé pẹ̀lú iyi Ati eye gege bi ìbòwò fún olórí.
“Ìgbà yìí jẹ́ àkókò ìrántí àti ìbùkún orílẹ̀-èdè,” ní gómìnà Abba Yusuf sọ.
Àtẹjáde náà tún sọ pé àtúnṣe ààbò pelu awon eso alabo ti wà ni-ile kí ìbẹ̀wò náà lè lọ dáadáa àti ní ìtẹ̀lọ́run.

